Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 10:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nádábù àti Ábíhù tí í ṣe ọmọ Árónì sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àìmọ́ níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa.

2. Torí èyí iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa.

3. Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí p锓 ‘Ní àárin àwọn tó súnmọ́ mi,Èmi yóò fí ara mi hàn ní mímọ́ojú gbogbo ènìyànNí a ó ti bu ọlá fún mi’ ”Árónì sì dákẹ́.

4. Mósè pe Másáélì àti Élísáfánì ọmọ Yúsíélì tí í ṣe arákùnrin Árónì, ó sọ fún wọn pé “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.”

5. Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mósè ti sọ.

6. Mósè sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù, Élíásárì àti Ítamárì pé, “ẹ má ṣe sọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ sí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.

Ka pipe ipin Léfítíkù 10