Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 8:28-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Jóṣúà sì jó Áì, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí.

29. Ó sì gbé ọba Áì kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí òòrùn sì ti wọ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkítì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.

30. Nígbà náà ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan fún Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní òkè Ébálì,

31. gẹ́gẹ́ bí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú Iwé Òfin Móṣè, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí. Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbo ṣísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí i rẹ̀ sí Olúwa.

32. Níbẹ̀ ní ojú àwọn ará Ísírẹ́lì, Jósúà sì ṣe àdàkọ òfin Mósè èyí tí ó ti kọ sí ara òkúta náà.

33. Gbogbo Ísírẹ́lì, àlejò àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní Òkè Gérísímù, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ébálì, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.

34. Lẹ́yìn èyí, Jóṣúà sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin ìbùkún àti ègún-gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Òfin.

35. Kò sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mósè pàṣẹ, tí Jósúà kò kà ní iwájú gbogbo àjọ Ísírẹ́lì, títí fi kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin wọn.

Ka pipe ipin Jóṣúà 8