Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 8:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jóṣúà pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ ogun pẹ̀lúù rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Áì. Nítorí mo ti fi ọba Áì, àwọn ènìyàn an rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

2. Ìwọ yóò sì ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.”

3. Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun jáde lọ láti dojú kọ Áì. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru.

4. Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáadáa. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúra-sílẹ̀.

5. Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lúù mi yóò súnmọ́ ìlú náà; Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì ṣá kúrò níwájú u wọn.

6. Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sá lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú. Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn,

7. ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà. Olúwa Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Jóṣúà 8