Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 7:14-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “ ‘Ní òwúrọ̀ kí ẹ mú ará yín wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan.

15. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!’ ”

16. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì, Jóṣúà mú Ísírẹ́lì wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Júdà.

17. Àwọn agbo ilé e Júdà wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sérátì. Ó sì mú agbo ilé Sérátì wá ṣíwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Símírì.

18. Jóṣúà sì mú ìdílé Símírì wá ṣíwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Sérà ti ẹ̀yà Júdà.

19. Nígbà náà ní Jóṣúà sọ fún Ákánì pé, “Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí o sì fi ìyin fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.”

20. Ákánì sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Nǹkan tí mo ṣe nì yí:

21. Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Bábílónì kan tí ó dára nínú ìkógún, àti igba sẹ́kélì fàdákà àti díndi wúrà olóṣùnwọ̀n àádọ́ta ṣẹ́kélì, mo ṣe ojú kòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ ọ̀ mi àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀.”

22. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì ṣáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀.

23. Wọ́n sì mú àwọn nǹkan náà jáde láti inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n mú wọn wá fún Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi wọ́n lélẹ̀ níwájú Olúwa.

24. Nígbà náà ni Jóṣúà pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, mú Ákánì ọmọ Sérà, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi àfonífojì Ákórì.

25. Jóṣúà sì wí pé, “Èé ṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí i wa? Olúwa yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.”Nígbà náà ni gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tó kù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná.

Ka pipe ipin Jóṣúà 7