Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 3:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì; kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lúù rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Móṣè.

8. Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà: ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jọ́dánì, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ”

9. Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín.

10. Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárin yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì, Hífì, Pérésì, Gágáṣì, Ámórì àti Jébúsì jáde níwájú u yín.

11. Àpótí ẹ̀rí Olúwa gbogbo ayé, ń gòkè lọ sí Jọ́dánì ṣáájú u yín.

12. Ǹjẹ́ nísinsìn yí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

13. Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹṣẹ̀ bọ odò Jọ́dánì, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbájọ bí òkítì kan.”

14. Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jọ́dánì, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn.

15. Odò Jọ́dánì sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jọ́dánì, tí ẹṣẹ̀ wọn sì kan etí omi,

16. omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbájọ bí òkítì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Ádámù, tí ó wà ní tòsí Sárétanì; nígbà tí omi tí ń ṣàn lọ sínú òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátapáta. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdì kejì ní ìdojúkọ Jẹ́ríkò.

17. Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárin Jọ́dánì, nígbà tí gbógbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀ èdè náà fi ré kọjá nínú odò Jọ́dánì lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Ka pipe ipin Jóṣúà 3