Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 22:11-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti mọ pẹpẹ ní orí ààlà Kénánì ní Gélíótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ìhà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,

12. gbogbo àjọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò láti lọ bá wọn jagun.

13. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà, sí ilẹ̀ Gílíádì, sí Rúbẹ́nì, sí Gádì àti sí ìdajì ẹ̀yà Mánásè.

14. Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ti wọn jẹ́ olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

15. Nígbà tí wọ́n lọ sí Gílíádì-sí Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè wọ́n sì sọ fún wọn pé,

16. “Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì nípa yíyí padà kúró lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìsọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa.?

17. Ẹ̀sẹ̀ Péórì kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-àrùn ti jà láàárin ènìyàn Olúwa.!

18. Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí.?“ ‘Tí ẹ̀yin bá sọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Ísírẹ́lì.

19. Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa.

20. Nígbà tí Ákánì ọmọ Sérà ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọtọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Ísírẹ́lì nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”

21. Nígbà náà ni Rúbénì, Gádì àti ẹ̀yà Mánásè sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Ísírẹ́lì pé.

22. Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀ jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìsọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa, ẹ má ṣe dá wa sí ní òní yìí.

23. Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san

24. “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yín ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì?

25. Olúwa ti fi Jódánì ṣe ààlà láàárin àwa àti ẹ̀yin-àwọn ọmọ Réúbénì àti àwọn ọmọ Gádì! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa.

26. “Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ọrẹ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’

27. Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàárin àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’

Ka pipe ipin Jóṣúà 22