Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 19:38-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Írónì, Mígídálì-Élì, Hórémù, Bẹ́tì-Ánátì àti Bẹ́tì-Sẹ́mẹ́ṣì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún àti ìletò wọn.

39. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Náfitalì, ní agbo ilé sí agbo ilé.

40. Ìbò keje jáde fún ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé ní agbo ilé.

41. Ilẹ̀ ìní wọn nì wọ̀nyí:Sórà, Éṣtaólì, Írí-Ṣẹ́mẹ́sì,

42. Ṣáálábínì, Áíjálónì, Ítílà,

43. Élónì, Tímínà, Ékírónì,

44. Élítékè, Gíbétónì, Báálátì,

45. Jéúdì, Béné-Bérákì, Gátí-Rímónì,

46. Mé Jákónì àti Rákónì, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Jópà.

47. (Ṣùgbọ́n àwọn ará Dánì ní ìsoro láti gba ilẹ̀-ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Lẹ́ṣẹ́mù, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Lẹ́sẹ́mù, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì orúkọ baba ńlá wọn).

48. Àwọn ìlú wọ̀n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé agbo ilé.

49. Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Ísírẹ́lì fún Jóṣúà ọmọ Núnì ní ìní ní àárin wọn

50. Bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n fún-ún ni ìlú tí ó béèrè fún—Tímínátì Sérà ní ìlú òkè Éfúráímù. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀.

51. Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Élíásárì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Ísírẹ́lì fi ìbò pín ní Sílò ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Jóṣúà 19