Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 15:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìpín fún ẹ̀yà Júdà, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbégbé Édómù, títí dé ihà Síní ní òpin ìhà gúsù.

2. Ààlà wọn ní ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúsù Òkun Iyọ̀,

3. Ó sì lọ sí gúsù Sikopioni Pasi lọ títi dé Sínì àti sí iwájú ìhà gúsù Kadesi Báníyà. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hésórónì lọ sí Ádárì, ó sì tún yípo yíká lọ sí Kákà.

4. Ó tún kọjá lọ sí Ásímónì, ó sì papọ̀ mọ́ Wádì ti Éjíbítì, ó parí sí òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúsù.

5. Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jọ́dánì.Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jọ́dánì,

6. ààlà náà sì tún dé Bẹti-Hógílà, ó sì lọ sí ìhà àríwá Bẹti-Árábà. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bóhánì ti ọmọ Rúbẹ́nì.

7. Ààlà náà gòkè lọ títí dé Débírì láti Àfonífojì Ákórì, ó sì yípadà sí àríwá Gílígálì, èyí tí ó dojú kọ iwájú Ádúmímù gúsù ti Gọ́ọ́jì. Ó sì tẹ̀síwájù sí apá omi Ẹbi Ṣéméṣì, ó sì jáde sí Ẹni Rógélì.

8. Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí Àfonífojì Bẹni Hínómù ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúsù ti Jébúsì (tí í ṣe Jérúsálẹ́mù). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí Àfonífojì Hínómù ní òpín àríwá àfonífojì Réfáímù.

9. Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Néfítóà, ó sì jáde sí ìlú Okè Éífírónì, ó sì lọ sí apá ìṣàlẹ̀ Báálà, (tí í ṣe, Kiriati Jéárímù).

10. Ààlà tí ó yípo láti Báálà lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí okè Séírì, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jéárímù (tí íṣe, Késálónì), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, ó sì kọja lọ sí Tímínà.

11. Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ékírónì, ó sì yípadà lọ sí Síkerónì, ó sì yípadà lọ sí Okè Báálà, ó sì dé Jábínẹ́ẹ́lì, ààlà náà sì parí sí òkun.

12. Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá.Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn.

13. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Jóṣúà, ó fi ìpín fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, ipin ní Júdà-Kiriati Áríbà, tí í ṣe Hébúrónì. (Áríbà sì ní baba ńlá Ánákì.)

14. Kélẹ́bù sì lé àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta jáde láti Hébúrónì-Ṣéṣáyì, Áhímónì, àti Tálímáì-ìran Ánákì.

Ka pipe ipin Jóṣúà 15