Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 11:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jábínì ọba Hásórù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Madónì, sí ọba Ṣímírónì àti Ákíṣáfù,

2. àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúsù ti Kínérótù, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafotu Dórì ní ìwọ̀-oòrùn;

3. sí àwọn ará Kénánì ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Ámórì, Hítì, Pérísì àti Jébúsì ní orí òkè; àti sí àwọn Hífì ní ìsàlẹ̀ Hámónì ní agbégbé Mísípà.

4. Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun

5. Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.

6. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromù, wọ́n sì kọlù wọ́n,

8. Olúwa sì fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sídónì ńlá, sí Mísíréfótì-Máímù, àti sí Àfonífojì Mísípà ní ìlà-óòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.

9. Jóṣúà sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ: Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.

10. Ní àkókò náà Jóṣúà sì padà sẹ́yìn, ó sì ṣẹ́gun Hásórù, ó sì fi idà pa ọba rẹ̀. (Hásóri tí jẹ́ olú fún gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí Kó tó di àkókò yí.)

11. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátapáta, wọn kò sì fi ohun alàyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hásóri fúnrarẹ̀.

12. Jóṣúà sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.

13. Sí bẹ̀ Ísírẹ́lì kò sùn ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kékèké, àyàfi Hásórì nìkan tí Jóṣúà sun.

14. Àwọn ará Ísírẹ́lì sì kó gbogbo ìkógún àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátapáta, kò sí ẹni tí ó wà láàyè.

Ka pipe ipin Jóṣúà 11