Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 10:24-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Jóṣúà wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ sún mọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.

25. Jóṣúà sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀ta yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”

26. Nígbà náà ni Jóṣúà kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba máràrùn náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.

27. Nígbà tí oòrun wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ, wọ́n sì ṣọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúró ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sápamọ̀ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

28. Ní ọjọ́ náà Jóṣúà gba Mákédà. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátapáta, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Mákédà gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò.

29. Nígbà náà ní Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Mákédà lọ sí Líbínà wọ́n sì kọlù ú.

30. Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Jóṣúà fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò.

31. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo ará Ísírẹ́lì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Líbínà lọ sí Lákíṣì; ó sì dótì í, ó sì kọlù ú.

32. Olúwa sì fi Lákísì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sì gbà á ní ọjọ́ kéjì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pá gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Líbínà.

33. Ní àkókò yìí, Hórámì ọba Gésérì gòkè láti ran Lákíṣì lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Jóṣúà ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀.

34. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lákíṣì lọ sí Égílónì; wọ́n sì dótì í, wọ́n sì kọ lù ú.

Ka pipe ipin Jóṣúà 10