Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 1:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ikú u Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Jóṣúà ọmọ Núnì, olùrànlọ́wọ́ ọ Móṣè:

2. “Mósè ìránṣẹ́ ẹ̀ mi ti kú. Nísinsìn yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ múra láti kọjá odò Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Ísírẹ́lì.

3. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Móṣè.

4. Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti ihà u Lẹ́bánónì, àti láti odò ńlá, ti Éfúrétì—gbogbo orílẹ̀ èdè Hítì títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.

5. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú ù rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mósè, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú ù rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

6. “Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le; nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí; láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

7. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì sọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Móṣè ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.

8. Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu ù rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀ṣán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.

9. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì se rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú ù rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

10. Báyìí ni Jóṣúà pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀

11. “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, Ẹ pèṣè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jọ́dánì yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.”

12. Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ará a Rúbẹ́nì, àwọn ará Gádì àti fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè pé,

Ka pipe ipin Jóṣúà 1