Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ikú u Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Jóṣúà ọmọ Núnì, olùrànlọ́wọ́ ọ Móṣè:

2. “Mósè ìránṣẹ́ ẹ̀ mi ti kú. Nísinsìn yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ múra láti kọjá odò Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Ísírẹ́lì.

3. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Móṣè.

4. Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti ihà u Lẹ́bánónì, àti láti odò ńlá, ti Éfúrétì—gbogbo orílẹ̀ èdè Hítì títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.

5. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú ù rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mósè, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú ù rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

6. “Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le; nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí; láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

7. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì sọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Móṣè ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.

8. Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu ù rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀ṣán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.

9. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì se rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú ù rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

10. Báyìí ni Jóṣúà pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀

Ka pipe ipin Jóṣúà 1