Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 6:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ẹ̀yin ènìyàn Bẹ́ńjámínì, sá síbi ààbò!Ẹ sá kúrò ní Jérúsálẹ́mù,Ẹ fọn fèrè ní Tékóà!Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Bẹti-Ákérémù!Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,àní ìparun tí ó lágbára.

2. Èmi yóò pa ọmọbìnrin Síónì run,tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.

3. Olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbógun tì wọ́n.Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”

4. “Múra sílẹ̀ láti bá a jagun!Dìde, kí a kọ lù ú ní ìgbà ọ̀sán!Àmọ́ ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.

5. Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọ lù ú ní àṣálẹ́kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

6. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jérúsálẹ́mù ká.A gbọdọ̀ fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè yìínítorí pé ó kún fún ìrẹ́nijẹ.

7. Gẹ́gẹ́ bí kàǹga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.Ìwà ipá àti ìparun ń tún dún padà nínú rẹ̀;nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.

8. Ìwọ Jérúsálẹ́mù, gba ìkìlọ̀kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,tí kò ní ní olùgbé.”

9. Èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí:“Jẹ́ kí wọn pesẹ́ ìyókù Ísírẹ́lìní tónítóní bí àjàrà;na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí igẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èṣo àjàrà jọ.”

10. Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àtití mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta niyóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọnti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.

11. Èmi kún fún ìbínú Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àtisórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kórawọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a òmú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbótí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.

12. Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,oko wọn àti àwọn aya wọn,nígbà tí èmi bá na ọwọ́ misí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 6