Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:59-64 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

59. Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì pàṣẹ fún Seráíyà, ọmọ Néríà, ọmọ Mááséíyà, nígbà tí o ń lọ ni ti Ṣedekáyà, Ọba Júdà, sí Bábílónì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Séráíà yí sì ní ìjòyè ibùdó.

60. Jeremáyà sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Bébálì sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ wọ̀nyí tí a kọ sí Bábílónì.

61. Jeremáyà sì sọ fún Séráíà pé, “nígbà tí ìwọ bá dé Bábílónì, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

62. Kí ìwọ kí ó sì wí pé, ‘Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé.’

63. Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá parí kíka ìwé yìí tán kí ìwọ kí ó di òkúta mọ́ ọn, kí ó sì sọ ọ́ sí àárin odò Éfúrétè:

64. Kí ìwọ sì wí pé, ‘Báyìí ní Bábílónì yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀: àárẹ̀ yóò sì mú wọn.’ ”Títí dé ìhín nií ọ̀rọ̀ Jeremáyà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51