Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 49:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nípa ìṣubú ariwo wọn, ilẹ̀yóò mì, a ó gbọ́ igbe wọnní òkun pupa.

22. Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bóráṣà.Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagunÉdómù yóò dàbí ọkan obìnrin tí ń rọbí.

23. Nípa Dámásíkù:“Inú Hámátì àti Árípádì bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,wọ́n sì dààmú bí omi òkun.

24. Dámásíkù di aláìlera, ó pẹ̀yindàláti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a,ìbẹ̀rù àti ìrora dì í mú, ìrorabí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.

25. Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;ìlú tí mo dunnú sí.

26. Lóòtọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹyóò ṣubú lójú pópó, gbogboàwọn ọmọ ogun rẹ yóò paẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

27. “Èmi yóò fi iná sí odi Dámásíkù,yóò sì jó gbọ̀ngàn Bẹni-hádádì run.”

28. Nípa Kédárì àti ìjọba Ásọ́rì èyí ti Nebukadinésárì Ọba Bábílónì dojú ìjà kọ:Èyí ni ohun tí Olúwa sọ:“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ kédárì,kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà oòrùn run.

29. Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọnyóò di gbígbà; ilé wọn yóò diìsínípò padà pẹ̀lú ẹrù àti ràkúnmí wọn.Àwọn ọkùnrin yóò ké pè wọ́n;‘Ìparun ní ibi gbogbo.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 49