Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 47:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremáyà wá nípa àwọn Fílístínì, kí ó tó di pé Fáráò dojúkọ Gásà:

2. Báyìí ni Olúwa wí:“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.Wọn ò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.Àwọn ènìyàn yóò kígbe;gbogbo ẹni tó ń gbé lórí ilẹ̀ yóò pohùnréré ẹkún

3. Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹlẹ̀ pátakò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbáranígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńláàti iye kẹ̀kẹ́ wọn.Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;ọwọ́ wọn yóò kákò.

Ka pipe ipin Jeremáyà 47