Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 44:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Éjíbítì ní Mígídò, Táfánásì àti Mémífísì àti ní apá òkè Íjíbìtì:

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Wo ibi tí mo mú bá Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ìlú Júdà. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun.

3. Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀.

4. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun búburú tí èmi kò fẹ́.’

5. Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró.

6. Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Júdà àti òpópó Jérúsálẹ́mù àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.

7. “Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Júdà ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?

Ka pipe ipin Jeremáyà 44