Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 42:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ ṣíwájú mi.

10. Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkan padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín.

11. Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ọba Bábílónì tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbàyín ní ọwọ́ rẹ̀.

12. Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’

13. “Àmọ́ ṣá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín.

14. Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Éjíbítì; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’

15. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Júdà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Éjíbítì láti lọ ṣe àtìpó ńibẹ̀.

16. Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyànu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Éjíbítì àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí.

17. Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Éjíbítì ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹníkẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’

18. Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà sita sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Éjíbítì. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹní ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 42