Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 32:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Jeremáyà wí pé, “ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

7. Hánámélì ọmọkùnrin Sálúmù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sún mọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’

8. “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.

9. Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Ánátótì láti ọwọ́ Hánámélì ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Ó sì wọn ìwọn ṣékélì àti fàdákà mẹ́tadínlógún fún un.

10. Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí síi, mo sì wọn fàdákà náà lórí òṣùwọ̀n.

11. Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀.

12. Èmi sì fi èyí fún Bárúkì ọmọkùnrin ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá túbú.

13. “Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Bárúkì pé:

14. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀.

15. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí.

16. “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Bárúkì ọmọkùnrin Néráyà, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:

17. “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbogbo, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe.

18. O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀gbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́rùn títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.

19. Títóbi ni iṣẹ́ rẹ, agbára sì ni ìṣe rẹ. Ojú rẹ sí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọkùnrin, ó sì fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti ìwà rẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 32