Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 32:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. O kó àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ jáde láti Éjíbítì pẹ̀lú àmì àti ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá.

22. Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.

23. Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o paláṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.

24. “Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe korájọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kálídéà tí ń gbógun tì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i.

25. Ṣíbẹ̀ à ò fi ìlú náà fún àwọn ará Kálídéà. Ìwọ Olúwa Ọba sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”

26. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá pé:

27. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran ara. Ǹjẹ́ ohun kan há a ṣòro fún mi bí?

28. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: Èmi ṣetan láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kálídéà àti fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ẹni tí yóò kó o.

29. Àwọn ará Kálídéà tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ ní ọ̀nà ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rúbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Báálì ti wọn sì ń da ẹbọ òróró fún Ọlọ́run mìíràn.

30. “Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti Júdà kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójúmi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Isreli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí

Ka pipe ipin Jeremáyà 32