Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 3:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Èmi fúnra mi sọ wí pé,“ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrinkí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.

20. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi.Ìwọ ilé Ísírẹ́lì”ni Olúwa wí.

21. A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.

22. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.”“Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹnítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.

23. Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrùkèrudò tí ó wà ní àwọn orí òkèkékèké àti àwọn òkè gíga;Nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́runwa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà.

24. Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú tipa èso iṣẹ́ àwọn baba wa,ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

25. Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀.A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa,àwa àti àwọn baba wa,láti ìgbà èwe wa títí di ònía kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 3