Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 29:20-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin àtìpó, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

21. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run sọ nípa Áhábù ọmọ Kóláháyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Máséà tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.

22. Nítorí ti wọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Bábílónì láti Júdà: ‘Ọlọ́run yóò ṣe yín bí i Sedekáyà àti Áhábù tí Ọba Bábílónì dáná sun.’

23. Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Ísírẹ́lì, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí.

24. Wí fún Ṣemáyà tí í ṣe Neelamíyà pé,

25. “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé,

26. ‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jéhóíádà láti máa jẹ́ alákóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.

27. Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrin yín?

28. Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Bábílónì wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29. Sefanáyà àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jérúsálẹ́mù tí í ṣe wòlíì.

30. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé,

Ka pipe ipin Jeremáyà 29