Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 29:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ẹ lè sọ pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì.”

16. Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa nípa Ọba tó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú náà; àní àwọn ènìyàn ìlú yín tí kò lọ sí ilé àtìpó pẹ̀lú yín.

17. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára wí pé: “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn sí wọn; Èmi yóò sọ wọ́n dà bí ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ.

18. Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni Èmi yóò fi lé wọn; Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, àti ohun ẹ̀gún àti ẹ̀rù; ohun ẹ̀gbin àti ohun ẹ̀dùn láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè ayé.

19. Nítorí wọ́n kọ̀ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ni ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin àtìpó, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

21. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run sọ nípa Áhábù ọmọ Kóláháyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Máséà tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.

Ka pipe ipin Jeremáyà 29