Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa nípa Ọba tó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú náà; àní àwọn ènìyàn ìlú yín tí kò lọ sí ilé àtìpó pẹ̀lú yín.