Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 28:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní oṣù karùn ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà Ọba Júdà, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì, tí ó wá láti Gíbíónì, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn:

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà Ọba Bábílónì rọrùn.

3. Láàrin ọdún méjì, mà á mú gbogbo ohun èlò tí Ọba Nebukadinésárì; Ọba Bábílónì kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Bábílónì padà wá.

4. Èmi á tún mú àyè Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Júdà ní Bábílónì,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò rọrùn.’ ”

5. Wòlíì Jeremáyà fún wòlíì Hananáyà lésì ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa.

6. Ó sọ wí pé, “Àmín! Kí Olúwa ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa ó mú àwíṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn aṣàtìpó padà sí ilẹ̀ Bábílónì.

7. Nísinsìnyìí, tẹ́tí sí àwọn ohun tí mo sọ fún gbígbọ́ àti fún gbígbọ́ gbogbo ènìyàn.

8. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè.

9. Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olótítọ́ tí Olúwa rán, tí àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.”

10. Wòlíì Hananáyà gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì fọ́ ọ.

11. Ó sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni mà á fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì láàrin ọdún méjì.’ ” Jeremáyà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

12. Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananáyà ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremáyà wí pé:

13. “Lọ sọ fún Hananáyà, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní àyè wọn, wà á bá àjàgà onírin.

Ka pipe ipin Jeremáyà 28