Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 27:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé.

11. Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

12. Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekáyà Ọba Júdà wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè.

13. Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí kò bá sin Ọba Bábílónì?

14. Ẹ má ṣe fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin Ọba Bábílónì,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ eké ni wọ́n ń sọ fún un yín.

15. ‘Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”

16. Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Bábílónì,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn.

Ka pipe ipin Jeremáyà 27