Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 27:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ṣe ìjárá àti àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wé ọrùn rẹ.

3. Kí o rán ọ̀rọ̀ sí Ọba ti Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà.

4. Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ:

5. Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.

6. Nísinsìn yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.

7. Gbogbo orílẹ̀ èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè àti àwọn Ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.

8. “ ‘ “Àmọ́ tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀; Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.

9. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tabi àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Èyin kò ní sin Ọba Bábílónì.’

10. Wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé.

11. Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

12. Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekáyà Ọba Júdà wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè.

13. Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí kò bá sin Ọba Bábílónì?

Ka pipe ipin Jeremáyà 27