Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 26:10-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nígbà tí àwọn aláṣẹ Júdà gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin sí ilé Olúwa, wọ́n sì mú àyè wọn, wọ́n jòkòó ní ẹnu ọ̀nà tuntun ilé Olúwa.

11. Àwọn àlùfáà àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”

12. Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.

13. Nísinsìnyìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.

14. Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi.

15. Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”

16. Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ ogun.”

17. Lára àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà sì sún ṣíwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé,

18. “Míkà ti Mórásì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Heṣekáyà Ọba Júdà. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘A ó sì fa Síónì tu bí okoJérúsálẹ́mù yóò di òkítìàlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíibi gíga igbó.’

19. “Ǹjẹ́ Heṣekáyà Ọba Júdà tàbí ẹnikẹ́ni ní Júdà pa á bí? Ǹjẹ́ Heṣekáyà kò bẹ̀rù Olúwa tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ Olúwa kò há a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.”

20. (Bákan náà Úráyà ọmọ Ṣémáíà láti Kúríátì Jéárímù jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremáyà ti ṣe.

21. Nígbà tí Ọba Jéhóíákímù àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Úráyà gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Éjíbítì.

22. Ọba Jéhóíákímù rán Elinátanì ọmọ Álíbórì lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn.

23. Wọ́n sì mú Úráyà láti Éjíbítì lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Jéhóíákímù; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)

24. Áhíkámù ọmọ Sáfánì ń bẹ pẹ̀lú Jeremáyà, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.

Ka pipe ipin Jeremáyà 26