Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 23:28-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí.

29. “Ọ̀rọ̀ mi kò há a dàbí iná?” ni Olúwa wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?

30. “Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” Olúwa wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn.

31. Bẹ́ẹ̀,” ni Olúwa wí, “Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ wí pé, ‘Olúwa wí.’

32. Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni Olúwa wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi sìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni Olúwa wí.

33. “Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, ‘Kí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa?’ Sọ fún wọn wí pé, ‘ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ wo? Èmi yóò pa yín tì ni Olúwa wí.’

34. Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa.’ Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.

35. Èyí ni ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ọ̀rẹ́ àti ará ilé rẹ̀: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa?’ tàbí ‘Kíni ohun tí Olúwa sọ?’

36. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ Olúwa’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára alààyè padà.

37. Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa sí ọ́?’ tàbí ‘Kí ni ohun tí Olúwa bá ọ sọ?’

38. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ó ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe gbà á, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 23