Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 22:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. “Dájúdájú bí èmi ti wà láàyè,” ni Olúwa wí, “Bí Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.

25. Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì àti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì.

26. Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.

27. Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”

28. Ǹjẹ́ Jéhóíákínì ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókèsí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.

29. Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀,gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

Ka pipe ipin Jeremáyà 22