Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 20:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó mú kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu ọ̀nà ti Bẹ́ńjámínì ní Tẹ́ḿpìlì Olúwa.

3. Ní ọjọ́ kejì tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremáyà sì sọ fún un wí pé, “orúkọ Olúwa kì í ṣe Páṣúrì fún ọ bí kò ṣe ohun ẹ̀rù.

4. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Júdà lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Bábílónì tàbí kí ó pa wọ́n.

5. Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀ta wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá Ọba Júdà. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Bábílónì.

6. Àti ìwọ Páṣúrì, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Bábílónì. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”

7. Olúwa, o tàn mí jẹ́,o sì ṣẹ́gun.Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.

8. Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe sítaèmi á sọ nípa ipá àti ìparun.Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkùàti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.

9. Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹtàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mití a sé nínú egungun miAgara dá mi ní inú minítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.

Ka pipe ipin Jeremáyà 20