Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 2:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódàtí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹàbàwọ́n àìṣedéédéé rẹ sì ń bọ̀ níwájú mi,”ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.

23. “Báwo ni o ṣe le lọ sọ pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́;Èmi kò ṣáà tẹ̀lé àwọn Báálì’?Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;wo ohun tí o ṣe.Ìwọ jẹ́ abo ìbákasíẹ̀tí ń sá sí ìhín sọ́hùn ún.

24. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń gbé ihàtí ń fa ẹ̀fúùfù nínú ìfẹ́ inú rẹ̀ta ni ó le è mu dúró ní àkókò rẹ̀?Kí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ílé e má ṣe dára wọn lágaranítorí wọn ó ò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.

25. Má ṣe sáré títí ẹṣẹ̀ yín yóò fi wà ní ìhòòhò,tí ahọ́n yín yóò sì gbẹ.Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Kò nílò!Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,èmi yóò sì lépa wọn lọ.’

26. “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójú ti olènígbà tí a bá mú u,bẹ́ẹ̀ náà ni ilé Ísírẹ́lìyóò gba, àwọn ìjòyè wọn,àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Jeremáyà 2