Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 19:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Báálì láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sí Báálì. Nǹkan ni èmi kò pa láṣẹ tàbí dárúkọ tí kò sì wá láti inú ọkàn mi.

6. Nítorí náà sọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn tí a kì yóò pe ibí ní Tófẹ́tì tàbí ọmọ Hininómù, ṣùgbọ́n Àfonífojì ìpakúpa.

7. “ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Júdà àti Jérúsálẹ́mù run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mi wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.

8. Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.

9. Èmi yóò mú kí wọn jẹ ẹran ara ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ ẹran ara wọn lásìkò ìparun wọn láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’

10. “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní oju àwọn tí ó bá ọ lọ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 19