Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 18:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun.

8. Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.

9. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan.

10. Tí ó sì ṣe búburú ní ojú mi, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni èmi yóò tún ṣe rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún wọn.

11. “Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe.’

12. Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò se nǹkànkan, àwa yóò tẹ̀ṣíwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọkan wa, yóò tẹ̀lé agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Ẹ bèèrè nínú orílẹ̀ èdè, ẹni tíó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?Ohun tí ó burú gidi ni wúndíá Ísírẹ́lì ti ṣe.

14. Ǹjẹ́ omi ojo rírí Lébánónì yóò diàwátì láti ibi àpáta? Sí omi tútùtí ó jìnnà sí orísun rẹ yóò kọ̀ láti ṣàn bí?

15. Síbẹ̀ ni àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi,wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà aṣántí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn àti ọ̀nà wọn àtijọ́.Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́ àti ní ojú tí a kò kọ́

16. Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì dinǹkan ẹ̀gàn títí láé. Gbogboàwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù, wọnyóò sì mi orí wọn.

17. Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn,Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọnní ọjọ́ àjálù wọn.”

18. Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremáyà, nítorí òfin ikọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò já sí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlùú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohun kóhun tí ó bá sọ.”

19. Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohuntí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 18