Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 15:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mósè àti Sámúẹ́lì dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!

2. Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí:“ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú;àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà;àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn;àwọn tí a kọ ìgbékùn mọ́ sí ìgbékùn.’

3. “Èmi yóò rán oríṣìí ìparun mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.

4. N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Mánásè ọmọ Heṣekáyà Ọba àwọn Júdà ṣe ní Jérúsálẹ́mù.

5. “Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jérúsálẹ́mù?Ta ni yóò dárò rẹ?Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?

6. O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí“Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́ lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run;Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.

7. Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọÈmi yóò fi atẹ fẹ́ wọn sí ẹnu ọ̀nàìlú náà. Èmi yóò mú ìsọ̀fọ̀ àti ìparunbá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọnkò tíì yí padà kúrò lọ́nà wọn.

8. Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ juyanrìn òkun lọ. Ní ọjọ́kanrí nièmi ó mú apanirun kọlu àwọnìyá ọmọkùnrin wọn. Lójìjì nièmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.

9. Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóòsì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹyóò wọ̀ lọ́sàn-án gangan, yóòdi ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmiyóò fi àwọn tí ó bá yè wá síwájúàwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”ni Olúwa wí.

10. Áà Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:ọkùnrin tí gbogbo ìtẹ́ tiraka tí wọ́nsì bá jà, èmi kò wín ni, bẹ́ẹ̀ nièmi ò yá lọ́wọ́ ẹni síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

Ka pipe ipin Jeremáyà 15