Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 12:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìní kò ha ti dàbíẹyẹ kanna-kánnátí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì kọ tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?Lọ kí o lọ ṣe àkójọ gbogbo àwọn ẹranko búburú,kó wọn wá láti wá parun.

10. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́ àgùntàn ni yóò sì ba oko àjàrà mi jẹ́,tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;Wọ́n ó sọ oko dídára mi diibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

11. A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀tí kò wúlò níwájú mi,gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoronítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.

12. Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ni àwọn apanirun ti gorí,nítorí idà Olúwa yóò paláti ìkángun kìn-ín-ní dé ìkángun ìkejì ilẹ̀ náà;kò sí ẹni tí yóò yè.

13. Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.Kí ojú kí ó tìyín nítorí èrè yín,nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.

14. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Júdà tu kúrò ní àárin wọn.

15. Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù.

16. Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘Olúwa ń bẹ,’ gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé, Olúwa wà a kọ́ ènìyàn mi láti fi Báálì búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrin ènìyàn mi.

Ka pipe ipin Jeremáyà 12