Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 7:19-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Wọn ó dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn ó sì dàbí èérí ìdọ̀tí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.

20. Wọn n ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀sọ́ wọn, tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, ní o sọ àwọn ǹnkan wọ̀nyí di ohun èérí tabi ìdọ̀tí fún wọn.

21. Èmi yóò sì fi àwọn ǹnkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àlejò àti fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn ó sì sọ ọ di aláìmọ́.

22. Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, wọn ó sì sọ ibi iṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀ wọn ó sì bà á jẹ́

23. “Rọ ẹ̀wọ̀n irin, torí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.

24. Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè ti búburú rẹ pọ̀ jù gba ilé wọn; ń ó sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.

25. Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn ó wá àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò ní sí

26. Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì sókè lórí ìdágìrì, Nígbà náà ni wọn ó wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì; ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn alàgbà.

27. Ọba yóò sọ̀fọ̀, ọmọ aláde yóò wà láì ní ìrètí ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn, nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 7