Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 7:15-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Idà wà níta, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹní tó bá wà ní orílẹ èdè, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.

16. Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedédé rẹ̀.

17. Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.

18. Wọn o wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn ó sì fá irun wọn.

19. Wọn ó dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn ó sì dàbí èérí ìdọ̀tí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.

20. Wọn n ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀sọ́ wọn, tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, ní o sọ àwọn ǹnkan wọ̀nyí di ohun èérí tabi ìdọ̀tí fún wọn.

21. Èmi yóò sì fi àwọn ǹnkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àlejò àti fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn ó sì sọ ọ di aláìmọ́.

22. Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, wọn ó sì sọ ibi iṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀ wọn ó sì bà á jẹ́

23. “Rọ ẹ̀wọ̀n irin, torí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.

24. Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè ti búburú rẹ pọ̀ jù gba ilé wọn; ń ó sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.

25. Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn ó wá àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò ní sí

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 7