Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 47:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àwọn ohun alààyè tí o ń rákò yóò máa gbé ní íbikíbi tí odò ti ń ṣàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń ṣàn síbẹ̀ ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń ṣàn gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè.

10. Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti Éńgédì títí dé Énégíláémù àyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Orísìírísìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi òkun ńlá.

11. Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀.

12. Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò dàgbà ní bèbè odò méjèèjì. Ewé wọn kì yóò sì gbẹ, tàbí ní èso nítorí pé odò láti ibi mímọ́ ń ṣàn sí wọn. Èso wọn yóò dàbí oúnjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”

13. Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Ọba wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárin àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ìpín méjì fún Jóṣéfù.

14. Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédéé ní àárin wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.

15. “Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà:“Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hétílónì gbà tí Hámátì sí Sídádì,

16. Bérótalì àti Síbíráímù (èyí tí ó wà ní ààlà láàárin Dámáskù àti Hámátì) títí dé Hásà Hátíkọ, èyí tí ó wà ní ààlà Háúránù.

17. Ààlà yóò fẹ̀ láti òkun lọ sí Hásà Énánù, ní apá ààlà ti Dámáskù, pẹ̀lú ààlà tí Hámátì lọ sí apá àríwá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá.

18. “Ní ìhà ìlà oòrùn ààlà yóò wá sí àárin Háúránù àti Dámásíkù, lọ sí apá Jọ́dánì láàárin Gílíádì àti ilẹ̀ oòrùn àti títí dé Támárì. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà oòrùn.

19. “Ní ìhà gúsù yóò lọ láti Támérì títí dé ibi omi méríba Kádési, lẹ́yìn náà ni ìhà wádìí tí Éjíbítì lọ sí òkun ńlá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúsù.

20. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hámátì. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀ oòrùn.

21. “Ìwọ ní láti pin ilẹ̀ yìí ní àárin ara yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

22. Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjòjì tí ó ń gbé ní àárin yín tí ó sì ní àwọn ọmọ. Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì; papọ̀ mọ́ yin ni kí a pín ìní fún wọn ní àárin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

23. Ní àárin ẹ̀yàkẹyà tí àwọn àlejò ń gbé; wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún-ún,” ní Olúwa Ọba pa lásẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 47