Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 45:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.

19. Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ilẹkùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ilẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú.

20. Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ kéje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.

21. “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àṣè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà.

22. Ní ọjọ́ náà ní ọmọ aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀sẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà.

23. Ní ojoojúmọ́ ni àárin ọjọ́ méje àṣè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

24. Òun yóò sì pèsè éfà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Éfà kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti éfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.

25. “ ‘Láàárin ọjọ́ méje àṣè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù kéje, òun yóò tún pèsè nǹkan bí ti tẹ́lẹ̀, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú òróró.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 45