Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 45:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí agbègbè mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀; gbogbo agbègbè náà ni yóò jẹ́ mímọ́.

2. Lára èyí, apákan ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí o jẹ́ ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní ó gbọdọ̀ wà fún ibi ìyàsímúmọ́ fún Ọlọ́run, pẹ̀lú ibẹ̀ tí ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún ilẹ̀ tí ó yí ibi mímọ́ náà ká. Ilẹ̀ tí ó yí i ká yìí yóò wà bẹ́ẹ̀ láì lò ó.

3. Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ.

4. Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa.

5. Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ yóò jẹ́ ti àwọn ará Léfì, tí ó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.

6. “ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.

7. “ ‘Àwọn ọmọ aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbégbé tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti apá ìwọ̀ oòrùn àti si ìlà oòrùn, láti apá ìlà oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀ oòrùn sí ààlà ìlà oòrùn, ti ìṣe déédéé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà.

8. Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 45