Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 44:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí: Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì!

7. Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjòjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkúlò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́.

8. Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi.

9. Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí: Àjòjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjòjì tí ń gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10. “ ‘Àwọn Léfì tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀sẹ̀ wọn.

11. Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rúbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

12. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Ísírẹ́lì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Ọba sọ.

13. Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti se ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn.

14. Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo isẹ́ tí a gbọdọ̀ se níbẹ̀.

15. “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì àti àwọn ìran Sádómù tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Ọba sọ.

16. Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ sùnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.

17. “ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run.

18. Wọ́n ní láti dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn.

19. Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń siṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí wọn kí ó má ba à sọ àwọn ènìyàn di mímọ́ nípasẹ̀ aṣọ wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 44