Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 44:12-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Ísírẹ́lì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Ọba sọ.

13. Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti se ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn.

14. Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo isẹ́ tí a gbọdọ̀ se níbẹ̀.

15. “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì àti àwọn ìran Sádómù tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Ọba sọ.

16. Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ sùnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.

17. “ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run.

18. Wọ́n ní láti dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn.

19. Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń siṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí wọn kí ó má ba à sọ àwọn ènìyàn di mímọ́ nípasẹ̀ aṣọ wọn.

20. “ ‘Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀.

21. Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú.

22. Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀; Wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó Àlùfáà.

23. Wọn ní láti fi ìyàtọ̀ tí ó wà nínú mímọ́ àti aláìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, kí wọn sì fi bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́ hàn wọ́n.

24. “ ‘Nínú èyíkéyi èdè-àìyedè, àwọn Àlùfáà ní ó gbọdọ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ fún gbogbo àṣẹ, wọn sì gbọdọ̀ lo ọjọ ìsinmi mi ní mímọ́.

25. “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ bàbá tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.

26. Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje.

27. Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti se ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Ọba wí.

28. “ ‘Èmi ni kì ó jẹ́ ogún tí àwọn Àlùfáà yóò ní. Ẹ kò gbọdọ̀ fún wọn ni ìpín kankan ní Ísírẹ́lì; Èmi ni yóò jẹ́ ìpín wọn.

29. Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ti wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 44