Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 40:44-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ. Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹ́ḿpìlì.

45. Ó sì wí fún mi pé, “yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà.

46. Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlúfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sádókù nínú àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.”

47. Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà.

48. Ó mú mi lọ sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì, ó sì wọn àwọn àtẹrígbà àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà; wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀. Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní fífẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì.

49. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ méjìlá láti iwájú dé ẹ̀yìn. Láti ara àtẹ̀gùn ní a ti ń dé ibẹ̀ àwọn òpó sì wà ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn àtẹ́rígbà náà.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 40