Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 4:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Júdà fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.

7. Dojú kọ ibùdó ogun Jérúsálẹ́mù, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

8. Èmi yóò dè ọ́ ní okùn débi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbógun tì rẹ yóò fi pé.

9. “Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá.

10. Wọn òṣùnwọ̀n ogún (20) ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ-lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀.

11. Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà hínì omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.

12. Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà báálì; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.”

13. Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

14. Nígbà náà ni mo wí pé, “Áà! kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Ọlọ́run! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsìnyìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”

15. Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò igbẹ ènìyàn.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 4