Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 4:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọn òṣùnwọ̀n ogún (20) ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ-lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀.

11. Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà hínì omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.

12. Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà báálì; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.”

13. Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

14. Nígbà náà ni mo wí pé, “Áà! kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Ọlọ́run! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsìnyìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”

15. Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò igbẹ ènìyàn.”

16. Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jérúsálẹ́mù. Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ́ jẹ pẹ̀lú ìfọ̀kansọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú,

17. nítorí pé oúnjẹ àti omi yóò wọ́n. Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú ìyanu, èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 4