Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 39:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́sin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìríṣìí jagunjagun ni Olúwa Ọba sọ.

21. “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.

22. Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Ísírẹ́lì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

23. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì subú nípasẹ̀ idà.

24. Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ̀ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

25. “Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọba wí: Èmi yóò mú Jákọ́bù padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní iyọ́nú si gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi.

26. Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìsòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnìkẹ́ni láti dẹ́rù bà wọ́n.

27. Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀.

28. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láì fi ìkankan sẹ́yìn.

29. Èmi kì yóò sì fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ nítorí èmi yóò tú èémí mi jáde sí ilé Ísírẹ́lì, ní Olúwa Ọba wí.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 39