Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 39:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ sí Gógù, kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ-aládé ti Mésékì àti Túbálì.

2. Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ. Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.

3. Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

4. Ìwọ yóò sì subú ní orí àwọn òkè Ísírẹ́lì, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó.

5. Iwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni Olúwa Ọba wí.

6. Èmi yóò fi iná sí mágógì àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

7. “ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrin àwọn èniyàn mì Isìrẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ èdè yóò mọ̀ pé èmi Olúwa, èmi ni ẹni mímọ́ ní Ísírẹ́lì.

8. Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́. Èyi yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

9. “ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárin àwọn ìlú tí ó wà ni Ísírẹ́lì yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ—àpáta kékèké àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná.

10. Wọn kò ní nílo láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lé òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́.

11. “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gógì ní Ísírẹ́lì, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà òòrùn òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn àjò, nítorí Gógì àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a óò pè é ní àfonífojì tí Ámónì Gógì.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 39