Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 37:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọwọ́ Olúwa wà lára mi, ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, ó mú kí ń wà ní àárin àfonífojì; ti o kún fún àwọn egungun.

2. Ó mú mi lọ síwájú àti sẹ́yìn láàrin wọn, èmi sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egungun ní orí ilẹ̀ àfonífojì, àwọn egungun tí ó gbẹ gan.

3. Olúwa sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?”Èmi sì wí pé, “Ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.”

4. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Ṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

5. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn egungun wọ̀nyí: Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè.

6. Èmi yóò so ìṣan ara mọ́ ọn yín, èmi yóò sì mú kí ẹran ara wá sí ara yín, èmi yóò sì fi awọ ara bò yín: Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

7. Nítorí náà ni mo ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń ṣọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun.

8. Mo wò ó, ìṣan ara àti ẹran ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.

9. Lẹ́yìn náà ni ó ṣọ fún mi pé, “Ṣọtẹ́lẹ̀ sí èémí; ṣọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì ṣọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 37