Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 30:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebìnígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò;níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópinwọn yóò fi ìkùukùu bò óàwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

19. Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Éjíbítì,wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

20. Ní ọjọ́ keje osù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

21. “Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣe apa Fáráò Ọba Éjíbítì. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a ko sì ti di i si àárin igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú.

22. Nítorí náà, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí Fáráò Ọba Éjíbítì. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.

23. Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Éjíbítì ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀.

24. Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a ṣá ní àṣápa.

25. Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì lé, ṣùgbọ́n apá Fáráò yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò sì fí idà náà kọlu Éjíbítì.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 30